scieee AI-readable full text Open interactive document viewer

Àtúngbéyẹ̀wò Ìlò Àti Ìṣesí Àwọn Ọ̀rọ À-So-Ọ̀rọ̀-Pọ̀ Ní Èdè Yorùbá

Olabode Thomas, Abimbola

Abstract

Ninú gírámà èdè Yorùbá, àwọn onímọ̀ gírámà ṣe àkíyèsí pé àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ kan wà tí wọ́n máa ń lò láti fi so ọ̀rọ̀, àpólà tàbí gbólóhùn méjì pọ̀. Ẹnu kò lórí ọ̀rọ̀-àsopọ̀ ti ẹyọ ọ̀rọ̀ àti àpólà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀wọ́ àwọn onímọ̀ kan náà tilẹ̀ sọ pé kò sí ohun tí a lè pè ní ọ̀rọ̀ àsopọ̀ tí ó ń so gbólòhùn pọ̀, àwọn onímọ̀ mìíràn sì gbà pé ó wà. Ohun tí a fẹ́ tẹpẹlẹmọ́ náà ni láti ṣàgbéyẹ̀wò ìlò ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rọ̀-àsopọ̀ wọ̀nyí, kí a mọ iye wọn, àti àwọn òté tó de ìlò wọn nínú èdè Yorùbá. A ṣe àkójọ àwọn détà lóríṣìíríṣìí láti inú àwọn onírúurú ìwé ti wọ́n kọ lédè Yorùbá àti ọ̀rọ̀ ẹnu àṣàyàn àwọn tí ń sọ èdè Yorùbá. A kò ṣàmúlò tíọ̀rì kankan nínú iṣẹ́ yìí kí a lè walẹ̀ jìn lórí àpèjúwe ìṣesí àtì ìhùwàsí àwọn ọ̀rọ̀-àsopọ̀ wọ̀nyí. Ohun tí a ṣe ni pé, a ṣàpèjúwe ìlò àti ìṣesí àwọn ọ̀rọ̀-àsopọ̀ ni. A rí i pé ọ̀rọ̀-àsopọ̀ Yorùbá wà ní abẹ́ ìsọ̀rí wúnrẹ̀n aṣegírámà nítorí àwọn àbùdá ìsọ̀rí náà tó pinminrin sínú rẹ̀. Bí a bá gùnlé ìlò àti ìṣesí wọn, a lè pín ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-àsopọ̀ Yorùbá sí ọ̀wọ́ méjì gbòòrò: àkọ́kọ́ ni ọ̀rọ̀-àsopọ̀ tí ó pín sí i: ọ̀rọ̀ a-so-ọ̀rọ̀/àpólà-pọ̀ àti ọ̀rọ̀ a-so-gbólóhùn-pọ̀. Èkejì ni ọ̀rọ̀-a-so-èjì-èrò-pọ̀ tàbí ọ̀rọ̀-asojú-sòdì-pọ̀/elérò ajárètí, ìsọ̀rí yìí náà pín sí: alábala méjì àti aláwẹ́ kan.

Full text

Journal of Indigenous Languages (JIL) - 2025 | http://journals.jozacpublishers.com/jil Vol. 3, No. 1, 2025 DOI: https://doi.org/10.5281/zenodo.17987700 Website: http://journals.jozacpublishers.com/jil Type of the Paper: (Journal Article) Àtúngbéyẹwò Ìlò Àti Ìṣesí Àwọn Ọrọ À-So-Ọrọ-Pọ Ní Èdè Yorùbá Olabode Thomas Abimbola1* 1*Department of Linguistics, African Languages & Communication Arts, Lagos State University (LASU), Ojo / Faculty of Arts, Lagos, Nigeria. [email protected] / [email protected] ORCID: https://orcid.org/0009-0004-2580-8185 Correspondence: [email protected] Received: July 16, 2025; Accepted: September 23, 2025; Published: December 19, 2025 Àṣamọ: Ninú gírámà èdè Yorùbá, àwọn onímọ gírámà ṣe àkíyèsí pé àwọn ọwọ ọrọ kan wà tí wọn máa ń lò láti fi so ọrọ, àpólà tàbí gbólóhùn méjì pọ. Ẹnu kò lórí ọrọ-àsopọ ti ẹyọ ọrọ àti àpólà. Bí ó tilẹ jẹ pé ọwọ àwọn onímọ kan náà tilẹ sọ pé kò sí ohun tí a lè pè ní ọrọ àsopọ tí ó ń so gbólòhùn pọ, àwọn onímọ mìíràn sì gbà pé ó wà. Ohun tí a fẹ tẹpẹlẹmọ náà ni láti ṣàgbéyẹwò ìlò ọkọọkan àwọn ọrọ- àsopọ wọnyí, kí a mọ iye wọn, àti àwọn òté tó de ìlò wọn nínú èdè Yorùbá. A ṣe àkójọ àwọn détà lóríṣìíríṣìí láti inú àwọn onírúurú ìwé ti wọn kọ lédè Yorùbá àti ọrọ ẹnu àṣàyàn àwọn tí ń sọ èdè Yorùbá. A kò ṣàmúlò tíọrì kankan nínú iṣẹ yìí kí a lè walẹ jìn lórí àpèjúwe ìṣesí àtì ìhùwàsí àwọn ọrọ- àsopọ wọnyí. Ohun tí a ṣe ni pé, a ṣàpèjúwe ìlò àti ìṣesí àwọn ọrọ-àsopọ ni. A rí i pé ọrọ-àsopọ Yorùbá wà ní abẹ ìsọrí wúnrẹn aṣegírámà nítorí àwọn àbùdá ìsọrí náà tó pinminrin sínú rẹ. Bí a bá gùnlé ìlò àti ìṣesí wọn, a lè pín ìsọrí ọrọ-àsopọ Yorùbá sí ọwọ méjì gbòòrò: àkọkọ ni ọrọ-àsopọ tí ó pín sí i: ọrọ a-so-ọrọ/àpólà-pọ àti ọrọ a-so-gbólóhùn-pọ. Èkejì ni ọrọ-a-so-èjì-èrò-pọ tàbí ọrọ-asojú-sòdì-pọ/elérò ajárètí, ìsọrí yìí náà pín sí: alábala méjì àti aláwẹ kan. Kókó-ọrọ: Ìsesí, Ọrọ-àsopọ, Òté-ìlò, Wúnrẹn aṣegírámà, Yorùbá Abstract: In Yoruba grammar, scholars have noted that there is a class of words which are used to connect words, phrases, and sentences together. Scholars seem to agree on the presence of lexical and phrasal conjunctions. Despite the fact that some scholars opined that there is nothing like a sentence conjunction in Yoruba, some scholars agreed that there is a sentence conjunction in the language. This work is not concerned with arguments about argument on the presence of sentence conjunctions or not. The main concern of the present work is to re-examine how each connective/conjunction is used, how many of them are used in numbers, and their usage constraints in the grammar of the Yoruba language. Syntactic structures are collated from various grammar texts and books written in the Yoruba language. No grammatical theory is adopted so as to give a detailed description of connective items’ syntactic behaviours in actual usage. It was discovered that conjunction is a subclass of functional items based on the prepondrance of grammatical features found in the words. If usage and syntactic beahviour are used as classifactory features, Yoruba connective items can be classified into two broad categories: the first is the conjunction which is sub-classified into lexical/phrasal conjunction and sentence conjunction. The second one is disjunction which is subclassified into: bi-structural and uni-structural disjunctions. Journal of Indigenous Languages (JIL) 173 of 185 Keywords: Conjunction, Grammatical item, Syntactic behaviour, Usage constraints, Yorùbá 1. Ìfáárà Àwọn àpẹẹrẹ ìhun gbólóhùn tó wà ní (1a-d) ní ìsàlẹ yìí, àwọn ọrọ kan wà tí a kọ níbùú àti ní àkọhàn oníbùú, a máa ń lò wọn gẹgẹ bí ọrọ tí a fi ń so ọrọ tàbí ìhun méjì pọ (Awobuluyi, 1978; Yusuf, 1999; Bamgbose, 1990; Yusuff, 2006 àti àwọn mìíràn). 1a) Ọlá àti/pẹlú Fọlá jẹ ọrẹ b) Òkùnrin dúdú náà àti/pẹlú àwọn èèyàn rẹ dúró de àlèjò pàtàkì d) Ní ọla àti/pẹlú ní ọtunla ni aputupu ó hu Àwọn ọrọ náà yàtọ ní ìṣesí àti ìtumọ wọn sí àwọn ọwọ tí a rí nínú ti ìsàlẹ wọnyí: 2a) Tọlá fẹràn ẹgbọn rẹ ṣùgbọn/àmọ Lọlá fẹràn àbúrò rẹ b) Adé kúrú, ó sì sanra Ohun tí àwọn onímọ fi yé wa ní pé, àwọn ọrọ tí a kọ ní àkọhàn wọnyí jẹ ọrọ-àsopọ. Bẹẹ sì ni pé, ìṣesí àti ìhùwàsí wọn nínú ìhun kò jọra. Àwọn onímọ kan gbà pé a lè so ọwọ àwọn ọrọ kan pọ láìlè so àwọn ọrọ mìíràn pọ pẹlú ọrọ-asopọ. Bẹẹ sì ni pé a máa ń ka gbogbo àwọn ọrọ náà sí abẹ ìsọrí kan náà. Púpọ nínú àwọn onímọ ni wọn ti ṣe akitiyan ní oríṣìíríṣìí láti sọ nípa àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí. Ṣùgbọn, nínú iṣẹ yìí, ohun tí ó jẹ àwa lógún gan-an ni láti ṣe àtúngbéyẹwò àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí láti mọ ìlò wọn, ìṣesí wọn, ọwọ tàbí ìpínsísọrí tí a lè kà wọn sí àti láti ṣàpèjúwe wọn bó tí tọ. Ìdí ni èyí tí a fi fẹ mọ ìdáhùnsí àwọn ìbéèrè iṣẹ ìwádìí yìí. A fẹ mọ bí ìṣesí, ìhùwàsí àwọn ọrọ-àsopọ ṣe rí ní èdè Yorùbá. Ṣé lóòtọ ni àwọn kan ṣeé pààrọ ara wọn láìfa ìyàtọ ìtumọ ìhun náà? Ǹjẹ gbobo wọn ni wọn jẹ ọrọ-àsopọ tabí àwọn kan ní ìsọrí mìíràn tó fara pẹ ti ọrọ-àsopọ? 2. Iṣẹ  àwọn ẹni ìṣáájú Gẹgẹ bí ó ṣe hàn nínú iṣẹ àwọn onímọ, oríṣìíríṣìí ọnà ni àwọn onímọ gírámà ti gbà láti ṣàpèjúwe ọrọ- àsopọ àti láti ṣàtúnpín wọn sí ọwọọwọ. Ní abala yìí, a ṣàgbéyẹyò ìṣẹ àwọn ẹni ìṣáájú lórí ọrọ-àsopọ láti mọ ibi tí iṣẹ dé àti ibi tí iṣẹ kù sí. Awóbùlúyì (1978) ki ọrọ-àsopọ gẹgẹ bí ọrọ tí ó ń fi òye pé ọrọ méjì tàbí jù bẹẹ lọ jọ lọ pọ tàbí pé wọn ti di ọkanhùn. Ìyẹn ni pé, ọrọ-àsopọ máa ń so ọrọ méjì tàbí àlòpọ-ọrọ pọ tí yóò sì fi yéni pé ìtumọ irú ọrọ bẹẹ jọ lọ pọ tàbí pé wọn yóò jọ ní ìtumọ kan náà. Ó ya irúfẹ àwọn ọrọ bí “àti”, “pẹlú” sọtọ gẹgẹ bí ọrọ-àsopọ, ó sì fi ṣàlàyé pé wọn yàtọ ní ìtumọ àti òye sí ìbátan wọn ọrọ a-so-èjì-ọrọ-pọ tí a mọ sí “disjunction” ní Gẹẹsì. Ìyẹn ni pé, wọn jọ ara wọn ní irúfẹ ìṣesí-gírámà tó dá lórí àyè wọn nínú ìhun, àti síso nǹkan pọ. Nítorí náà, Awobuluyi (1978) fi ìdí rẹ múlẹ pé, Yorùbá kò ní ọrọ-àsopọ fún gbólóhùn lẹyìn tí ó tọka sí “sì” pé ó jẹ aláìfìwàjọ ọrọ-àsopọ. Nítorí pé àwọn onímọ ìṣáájú wòye pé, gbólóhùn ni ó máa ń wà ní iwájú àwọn ìhun náà ni wọn ṣe kà wọn sí ọrọ-àsopọ gbólóhùn. Wọn ń fi òye pé èrò méjì jẹ ojú-àti-òdì ara wọn. Ìyẹn ni pé, gbógbó wọn kì í ṣe ọrọ-àsopọ. Bí a bá tẹlé èrò Awóbùlúyì (1978) yìí, a lè pín àwọn ọrọ tó lè so ọrọ pọ sí ọwọ méjì nípa lílo àbùdá ìṣọwọso-ọrọ-pọ tàbí àbájáde ìtumọ ìsopọ náà: ọrọ-àsopọ àti ọrọ-a-so-èjì-èrọ-pọ. Àmọ Awobùlúyì (1978) náà ni ó sọ pé àwọn elédè máa ń lo ọrọ-àsopọ lọpọ ìgbà láti fi yálà ìbáṣepọ tàbí ìṣòdìsí/ìyapa hàn. Awóbùlúyì (1978:106) tọka àwọn wọnyí: “àfi/àyàfi”, “àmọ”, “ṣùgbọn”, “bóyá...àbí/tàbí”, “yálà...àbí/tàbí”, àti “ańbọọsí/ańbọtorí/ańbẹlèńté/ańbẹlètàsẹ”. Yusuf (1980) náà tọka sí èrò Stockwell et. al. (1973) pé elédè máa ń lo ọrọ àsopọ láti fi ìbáṣepọ ọrọ hàn. Irú ìbáṣepọ náà lè jẹ ti ìjọra (similarity), ìjọṣẹlẹ (simultaneity), ṣísẹ-n-tẹlé (sequentiality), abbl. Journal of Indigenous Languages (JIL) 174 of 185 Èyí fi hàn pé, irú ọkanhùn ni wọn. Ọkan lára iṣẹ tí ọrọ-àsopọ ń ṣe ní ó hàn nínú ọrọ a-so-èjì-èrò-pọ. Ṣùgbọn, wọn yàtọ sí ọrọ-àsopọ gbólóhùn bíi ti “and” ní Gẹẹsì. Yusuf (198) náà tọka sí àwọn ọrọ wọnyí gẹgẹ bí ọrọ àsopọ lédè Yorùbá: àti, pẹlú, òun, àfi, àmọ, ṣùgbọn, bóyá...àbí/tàbí, yálà...àbí/tàbí, ańbọsí/bèlètàsé, síbẹsíbẹ, sì, bẹẹ ni. Bí a ṣe ń lo àwọn wúnrẹn ìyísódì wọnyí ni ó jẹ àwa lógún nínú iṣẹ yìí. Yusuf (1999) ki ọrọ àsopọ gẹgẹ bí ọrọ ti a fi ń so àpólà ọrọ tàbí gbólóhùn pọ. Oríkì yìí jọ ti àfimọ ti tíọrì gbé kalẹ nítorí pé nínú tíọrì olófin ìyídà, ẹyọ ọrọ lè ṣiṣẹ gẹgẹ bí àpólà orúkọ. Àmọ irú àpólà àti gbólóhùn tó ṣeé so pọ ni kò ṣàpẹẹrẹ rẹ fún wa. Èrò rẹ kò yàtọ sí ti Yusuf (1980) tí a ti mẹnubà ní ìṣáájú. Bámgbóṣé (1990: 189) ṣàlàyé pé “gbólóhùn alákànpọ ni èyí tí a fi ọrọ-àsopọ so àwọn gbólóhùn mìíràn pọ láti di ẹyọ kan”. Àmọ ṣá, kì í ṣe gbogbo ohun tí a bá fi ọrọ-àsopọ so pọ ni yóò ní ìtumọ kan. Bẹẹ sì ni pé kìí ṣe gbólóhùn nìkan ni a lè fi ọrọ-àsopọ so pọ nínú èdè Yorùbá. Bí ó tilẹ jẹ pé èrò yìí kò ki ọrọ-àsopọ gan-an, ó fún wa ní ìwòréré ìṣesí àwọn ọrọ-àsopọ. Ní ti Yusuff (2006: 37), ó ki ọrọ-àsopọ gẹgẹ “ọrọ tí ó ń so ọrọ pọ, so àpólà ọrọ pọ tàbí so gbólóhùn pọ”. Èyí dálé ọkan lára ìhùwàsí ọrọ-àsopọ àti irúfẹ nǹkan tó lè so pọ, tíí ṣe ọrọ, àpólà àti gbólòhùn. Bí a bá gùnlé oríkì ti Yusuff (2006) yìí, a ó kíyèsi pé kì í ṣe oríṣìí ọrọ-àsopọ kan ni ó wà látàri irúfẹ nǹkan tí wọn lè so pọ. Ó pín àwọn ọrọ-àsopọ sí ìsọrí pẹlú lílo àbùdá ìtumọ. Àwọn náà ni ọrọ-àsopọ oníjọra: àti/ti, pẹlú, òun. Ohun tí ó jẹ wọn lógún ni irúfẹ ìjọra tó wà núnú ìhun tí àwọn wúnrẹn àsopọ náà so pọ. Ṣùgbọn, wọn kò mẹnubà á pé ìjọra yìí kì í ṣe ti i rúfe  àbùdá ọ rọ  tí ó ń sọ ìhun méjè èjì pọ . ìtumọ  ni wọ n gùnlé. Àti pé, gbogbo bí elédè ṣe lè lo àwọn wúnrẹn náà ni àlàyé kò jìnlẹ tó lé lórí. Ó tilẹ sọ pé àgékúrú “àti” ni “ti” jẹ. Àti pé ìtumọ àkànlò ni ó sáábà máa jẹ. oríṣìríṣìí àríyànjiyàn ni ó wà lórí “tí” ní èdè Yọrùbá bíi Awóbùlúyì (2008) àti àwọn mìírà n tí wọ n ti me nuba ọ rọ  lórí re . Èkejì ni ọrọ-àsopọ oníyapa: “àyàfi/àfi”, “àmọ”, “ṣùgbọn”, “síbẹ”, “bóyá...tàbí/àbí”, “yálà...tàbí/àbí”, “ańbọsí/ańbèlètè/ańbọsìbọsí”. Àkópọ wà nínú ọwọ yìí. Bí a bá wo ìtumọ àwọn ọrọ wọnyí àti irúfẹ bí elédè ṣe ń lò wọn, yóò fojú hànde pé àkópọ lásán ni ó ṣẹlẹ níbí. Bẹẹ sì ni síbẹ gba àkíyèsí. Ọwọ kẹta ni ọrọ-àsopọ onítẹléǹtẹlé tíí ṣe sì. Ó ka “òun” sí ọrọ-àsopọ lòdì sí èrò Ìlọrí (2012) lóri “òun”. Bí ó tilẹ rí báyìí, àlàyé Yusuff (2006) fẹjú díẹ ju gbogbo àwọn yóòkù lọ àmọ kò tẹpelẹmọ ìṣesí àti ìhùwàsí nínú ìhun láti fi bí wọn ṣe rí hàn. Iṣẹ tí a fẹ ṣe ni àtúngbéyẹwò àti ìfẹlójú àwọn iṣẹ tó ti wà nílẹ àti láti tún mú èrò àti òye nípa àwọn ọrọ-àsopọ jinlẹ si. Ìlòrí (2010) ṣàgbèyẹwò ọrọ-àsopọ Yorùbá. Ọrọ àpọnlé aṣáájú ìṣe ni ó pè “sì”, tí “dẹ” jẹ ẹdà rẹ. Àlàyé rẹ dálé Tíọrì Oníwọba-Èròjà. Ó ní ìgbésíwájú ló fa kí ó máa jẹ yọ ní ibi tí ó ti ń jẹyọ. Ó gbà pé kò sí ọrọ-àsopọ tí ó dàbí “ṣùgbọn/àmọ” tí a lè pè ní ọrọ-a-so-gbólóhùn-pọ nínú èdè Yorùbá ní ìbámu pẹlú Awóbùlúyì (1978). Ìlọri (2012) wòye pé “òun” kì í ṣe ọrọ-àsopọ gẹgẹ bí ìmọ àtijọ ti fi hàn wá. Iṣẹ rẹ gan-an ni awẹyìn tí ó ń tọka sí ọrọ-orúkọ ìṣáájú. A faramọ èrò yìí nítorí pé kò sé, kò yà sí “òun” tíi ṣe ọrọ-arọpò orúkọ gígùn. Nítorí náà, “òun” kò sí lára àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí. Abimbola (2015 ) ṣàgbéyẹwò èrò àtijọ lórí ọrọ-àsopọ. Ó dálé àríyànjiyàn tó wà lórí “sì”, pé ṣé èdè Yorùbá ní ọrọ-àsopọ ti gbólóhùn àbí kò sí? Awóbùlúyì (1978) ti kọkọ ṣe àlàyé pé kò sí. Ṣùgbọn púpọ nínú àwọn onímọ gírámà bí Yusuff (2006), Ilori (2010), Abimbola (2015) àti àwọn mìíràn ni wọn gbà pé “sì” jẹ ọrọ-àsopọ. Èrò Abimbola (2015) ni pé, “sì” pé oríṣìí nínú èdè Yorùbá: sì atọka ìtẹnumọ, sì atọka ìṣẹlẹ ṣísẹ-n-tẹlé, sì tíi ṣe ọrọ-àsopọ. Yàtọ sí àwọn mẹta yìí, ó ní èdè Yorùbá ní ọrọ-àsopọ gbólóhùn onírìísí afarasin nínú àwọn gbólóhùn tí “sì” ti ń ṣiṣẹ gẹgẹ bí ìtẹnumọ tàbí ìṣẹlẹ ṣísẹ-n-tẹlé. Adékẹyè (2016) náà kí ọrọ àsopọ gẹgẹ bí wúnrẹn tàbí ọrọ tí ó ń só ẹyọ ọrọ, àpólà, tàbí odidi gbólóhùn pọ. Ṣùgbọn, èrò rẹ kò yàtọ sí àwọn àlàyé tó ti wà tẹlẹ. Abimbola (2024) náà fi kun pé ọrọ- àsopọ náà jẹ ọkan lára àwọn ọrọ aṣegírámà tàbí wúnrẹn aṣegírámà nítorí láìlò ó nínú ìhun a kò lè mọ Journal of Indigenous Languages (JIL) 175 of 185 ohun tó túmọ sí bí àwọn ọrọ bí ọrọ-ìṣe, ọrọ-orúkọ, àti àwọn mìíràn. Bí ó tilẹ jẹ pé a ti wo ọpọlọpọ àwọn oríkì kan tẹlẹ, kò sí èyí tó tọka sí àbùdá kan tí ìsọrí ọrọ-àsopọ ní bí ó ṣe hàn nínú oríkì yìí: ọrọ- àsopọ ni irúfẹ àwón ọrọ aṣegírámà tí wọn ń fi so ọrọ, àpólà, gbólóhùn méjì tàbí jù bẹẹ lọ pọ láti fi wọn hàn pé wọn ṣe ọkan ní èrò (Abimbola, 2024). Àbùdá kan tó ya ìsọrí ọrọ-aṣegírámà sọtọ ni pé a kò lè ṣẹdá ọrọ lára wọn tàbí kí a fi kún wọn nínú èdè bí a ti lè ṣe fún ọrọ-orúkọ àti ìsọrí àwọn ọrọ mìíràn. A kò lè fi kún ọrọ-àsopọ èdè Yorùbá, nítorí náà. A ó wo àwọn àbùdá tó sọ ọrọ-àsopọ di wúnrẹn tàbí ìsọrí ọrọ-aṣegírámà. 3. Ọgbọn Ìṣèwádìí A ṣe àmúlò àwọn fọnrán gbólóhùn tí ó ti wà nílẹ tẹlẹ nínú àwọn ìwé gírámà. A tún ṣàmúlò àwọn ìhun gbólóhùn tí a ti tò jọ fún àyẹwò ní onírúurú fún àkojọ dáta wa. Èròǹgbà wa ni pé bí a bá lè ṣàpèjúwe wọn dáadáa, òye nípa wọn yóò túnbọ jinlẹ ju tàtẹyìnwá lọ. 4. Ọrọ-àsopọ Yorùbá gẹgẹ bí wúnrẹn aṣẹgúir ámà Gẹgẹ bí a ti mẹnu bà á lókè pé Abímbọlá (2024) tọka pé ọrọ-àsopọ jẹ ọwọ ìsọrí aṣegírámà, wúnrẹn aṣegírámà ni ọwọ àwọn ọrọ tí wọn ní ìtumọ gírámà (tàbí èyí tí kò ní ìtumọ kankan), yàtọ sí àwọn ìsọrí-ọrọ aláìnítumọ gírámà tí wọn ní ìtumọ kíkún tí a lè tètè mọ (McIntyre, 2015:1). Ìyẹn ni pé láìmú wọn lò nínú ìhun gbólóhùn, kò ṣeé ṣe kí a lè tètè tọka ìtumọ tí àwọn wúnrẹn aṣegírámà ní. Ó tọka àwọn ọrọ bíi atọka aṣàfihàn, ọrọ-àsopọ, atọka amúpé àti àwọn yòókù. Èyí fi hàn pé ọrọ-àsopọ jẹ ọkan lára wọn bí a bá wo ìṣesí wọn ní ìbámu pẹlú oríkì wúnrẹn aṣegírámà òkè yìí. Bákan náà ni Rizzi àti Cinque (2016) sọ pé ìyàtọ àwọn ọrọ aṣegírámà àti ọrọ aláìṣegírámà yàtọ sí níní ìtumọ ajẹmọgírámà tí ó sábà máa ń jẹ mọ afòyemọ ni pé, àwọn ọrọ tàbí wúnrẹn aṣegírámà sábà máa ń ní: i) Ìhun/ìrísí fonọlọjì tó yàtọ. Àwọn ọrọ-àsopọ èdè Yorùbá máa ń sábà bẹrẹ pẹlú ìró kọńsónáǹtì. Púpọ nínú wọn ni wọn jẹ oní-sílébù méjì. Èdè Yorùbá ní ọwọ àwọn tí wọn jẹ ẹlẹlà bí a bá wo ìhun wọn tí abala ìhun tí wọn ń so pọ yóò sì wà láàárín. ii) Iye tó ṣeé kà nínú èdè. A kì í lè fi kún iye wọn nínú èdè. Bí iye àwọn ọrọ-àsopọ ṣe rí ní èyí fi hàn. A kò lè fi kún iye wọn ní èdè Yorùbá. iii) Àìlèṣẹdá ọrọ tuntun láti ara wọn. Ó jẹ àbùdá pàtàkì tí ó tún fi wọn hàn gẹgẹ bí wúnrẹn aṣegírámà nítorí a kò lè ṣẹdá ọrọ lára wọn. “Àti/ti” ni a sábà máa ń lè kànpọ pẹlú ọrọ-orúkọ ní èdè Yorùbá. yàtọ sí èyí tí a tọka yìí, ṣíṣẹdá ọrọ láti ara ọrọ-àsopọ Yorùbá kò ṣeé ṣe. iv) Wọn a máa ṣokùnfà gbígbé ọrọ síwájú nínú ìhun. Bí wọn bá ní àwọn àbùdá tó yẹ làti fi gbé ọrọ láti ibi kan sí ìbòmíràn, bíi ìtẹnumọ, àsọdọtọ, abbl, wọn á fa gbígbé ọrọ tàbí fọnrán-ìhun náà. Èyí ṣeé ṣe nígbà tí a bá tẹnumọ àpólà orúkọ alásopọ ní èdè Yorùbá. v) Wọn máa ń fa ìyípadà tàbí ìyàtọ ajẹmọ-ẹka-èdè nínú ìhun gírámà. Ní ọpọọgbà ni ó jẹ pé ìyàtọ ajẹmọhùn gíràmà máa ń wáyé tí ó sì jẹ pé àwọn wúnrẹn aṣegírámà ni ó máa ń ṣokùnfà wọn. Kódà, wọn lè mú kí ẹka-èdè kan yàtọ sí èkejì. Nínú àwọn ẹka-èdè Yorùbá kan ní a ti sábà máa ń bá àwọn ọrọ bíi “ańbẹlète”, “ańbèlètàsé”, abbl. pàdé. Bí a bá wo àwọn àbùdá wọnyí, a ó rí pé òótọ ni pé ọrọ-àsopọ èdè Yorùbá jẹ ìsọrí wúnrẹn aṣegírámà. Àfijọ kan tí àwọn wúnrẹn aṣegírámà ní pẹlú àwọn ìsọrí-ọrọ aláìṣegírámà ni pé wọn jọ máa ń jẹ oríìhun. Ọrọ-àsopọ lè jẹ orí-ìhun alásopọ nínú gírámà èdè Yorùbá. Àwọn onímọ tíọrì bíi ti tíọrì Oníwọnba Èròjà sábà máa ń tọka sí èyí. Ó tilẹ fẹẹ jẹ pé gbogbo ìhun ni ó ní wọnrẹn aṣegírámà tó gàbà lé wúnrẹn aláìṣegírámà ní ọnà kan tàbí òmíràn. Àmọ, iṣẹ ti wa kò ní nǹkan ṣe pẹlú tíọrì kankan bí kò ṣe pé kí a ṣe àlàyé ìṣàpèjú bí a ṣe ń lò wọn. Journal of Indigenous Languages (JIL) 176 of 185 Àtúnpínsísọrí ọrọ-àsopọ Ní abala yìí, ohun tó jẹ wá lógún ni láti yànnàná àwọn ọwọ tí a lè pín onírúurú àwọn ọrọ àsopọ sí fún ìṣàpèjúwe wọn. Oríṣìí ọnà ni a lè gbà pín àsopọ Yorùbá. Bí a bá gùnlé ohun tí wọn ń so pọ tàbí ìhunìsopọ gẹgẹ bí òṣùwọn tàbí àbùdá ajẹmọhun láti ṣàtúnpín wọn sí ọwọọwọ, a lè pín wọn sí ọwọ méjì: i) Ọrọ a-so-ọrọ-orúkọ/àpólà-pọ: àwọn wọnyí ni a ń lò láti fi so ẹyọ ọrọ/ọrọ orúkọ, ọrọ-arọpò orúkọ gígùn, àpólà orúkọ, àti àpólà àtọkùn pọ. Èyí ni ọrọ-a-so-ọrọ-orúkọ-pọ tàbí ọrọ-a-so-àpólàpọ. A ṣe àpèjúwe rẹ ní ìsàlẹ. Àpẹẹrẹ ni: “àti/ti” àti “pẹlú”. ii) Ọrọ a-so-gbólóhùn-pọ: gẹgẹ bí orúkọ rẹ, èyí ni àwọn ọrọ-àsopọ tí a ń lò láti fi so gbólóhùn pọ nínú èdè Yorùbá. A ṣe àpèjúwe wọn ní ìsàlẹ. Àpẹẹrẹ ni: sì, àti ọrọ-àsopọ onírísí afarasin. Bí a bá gùnlé àbájáde ìsopọ, ìṣọwọso-ọrọ-pọ tàbí àbájáde ìtumọ ìsopọ gẹgẹ bí òṣùwọn tàbí àbùdá, a lè pín àwọn ọrọ tó ń so ọrọ tàbí ìhun méjì pọ sí ọwọ méjì: i) Ọrọ-àsopọ (conjunction): Ọrọ-àsopọ ni àwọn wúnrẹn aṣegírámà tí a ń lò fi so ọrọ méjì, àpólà tàbí gbólóhùn méjì pọ láti fi hàn pé àbáyọrí ìtumọ àti ìhun wọn ṣe ọkan. Ọpọlọpọ àwọn wọnyí ni wọn wà nínú èdè Yorùbá láti so ẹyọ ọrọ méjì, àpólà orúkọ, àpólà atọkùn àti gbólóhùn pọ. ii) Ọrọ a-sojú-sòdì-pọ (disjunction): Ìbátan ọrọ-àsopọ ni ọwọ kejì yìí jẹ sí ọrọ-àsopọ. Àwọn wọnyí kò tí ì ní àpèjúwe tí ó tọ bó ti yẹ nínú àwọn ìwé gírámà ju kí wọn máa pè wọn ní ọrọ- àsopọ lọ. Wọn máa ń dúró sáàárín ìhun méjì tí wọn ń so pọ tàbí kí wọn dúró ní ìbẹrẹ abala ìhun tí a fẹ so pọ tí awẹ kan yóò sì jẹ mọọn-nú látàrí ìmọtẹlẹ tí àtolùgbọ àtolùsọ ti ní tẹlẹ. A tún lè pè wọn ní àwọn ọrọ a-so-èjì-èrò-pọ bí “ṣùgbọn”, “àmọ”, “àfi/àyàfi”. Bí a bá wo ìrísí tàbí mọfọlọjì àwọn ọrọ-àsopọ àti ọrọ asojúsòdìpọ gẹgẹ bí òṣùwọn, a lè pín gbogbo wọn sí ọwọ méta: i) Ọrọ-àsopọ aláwẹ-kan: Àwọn wọnyí ni ọrọ-àsopọ bí “àti/ti”, “pẹlú”, “àmọ”, “sì” tí wọn ní awẹ kan ṣoṣo. Wọn kò ṣe é là sí méjì. ii) Ọrọ asojúsòdìpọ aláwẹ-ìhun kan/alábala kan: Àpẹẹrẹ àwọn ọrọ asojúsòdìpọ aláwẹ kan ni “ṣùgbọn” àti “àmọ”, “ańbọsí/ańbọtorí/ańbèlètàsé/ańbọsìbọsí” àti “síbẹsíbẹ”. Wọn sì máa ń dúró láàárín wúnrẹn méjì tí wọn ń so pọ. iii) Ọrọ-àsopọ aláwẹ-méjì/alábala-méjì: Àpẹẹrẹ àwọn wọnyí ni: “yálà...tàbí/àbí”, “bóyá...tàbí/àbí”, Àbùdá ajẹmérò: Bí a bá gùnlé èrò, a lè wò ó pé ṣe èrò náà ṣọkan tàbí èrò náà jẹ alójú-lódì tàbí oníyíyan èrò kan péré. Bí a bá wo ìye èrò tó wà nínú ìhun tí a ní a lè pin sí: i) Elérò aṣọkan: Èrò kan péré ni àwọn wọnyí ń ṣàfihàn. ii) Elérò atakora tàbí alójúlódì: èrò méjì tí wọn jẹ òdì ara wọn ni àwọn wọnyí ń ṣàfihàn iii) Oníyíyan èrò kan: Àwọn wọnyí jẹ mọ yíyan èrò kan péré nínú méjì tó wà nílẹ. Àbùdá ajẹmọ-ìlò: Èyí ni ọnà tí a gbà lo àwọn ọrọ-àsopọ gẹgẹ ọnà láti pín wọn sí ìsọríìsọrí. Bí a bá gùnlé àbùdá yìí, a lè pín sí i) Oníyíyàn: O gbà pé kí a yan ọkan nínú ohun tí ó wà nílẹ. ii) Aláìgbayíyàn: Èyí kò fàyè gba yíyàn láàárín ohun méjì. Ní abala tó kàn ni a ti ṣe àpèjúwe ìlò ìkọọkan àwọn ọrọ àsopọ àti ọrọ asojúsòdìpọ láti lè fa òté tí ó de ìlò wọn yọ. Journal of Indigenous Languages (JIL) 177 of 185 Ọrọ- A-so-ọrọ-orúkọ-pọ tàbí Ọrọ-a-so-àpólà-pọ Èyí ni àwọn ọrọ-àsopọ tí wọn ń so ọrọ-orúkọ, ọrọ-arọpò orúkọ gígùn, àpólà orúkọ àti àpólà àtọkùn pọ. Ní àkọkọ, bí a bá yọ ọwọ “òun” kúró nínú wọn, yóò ku méjì péré: “àti” àti “pẹlú”. Bí ó ti lẹ jẹ pé ọrọ tàbí àpólà ni a fi ń so pọ, a kì í fi so ọrọ-arọpọ-orúkọ kúkúrù, ọrọ-ìṣe, àpólà ìṣe, ọrọ-àpejúwe, ẹyán, ẹpọn àti àwọn wúnrẹn aṣegíràmà pọ ní èdè Yorùbá. Ọwọ yìí ni ìsọrí àwọn ọrọ-àsopọ tàbí a-so-ọrọ- pọ tí wọn máa ń lò báyìí. i) Ọrọ-orúkọ + ọrọ-orúkọ (OR+OR): A lè èyíkéyìí nínú àwọn àti àti pẹlú láti fi so àwọn ọrọ orúkọ méjì pọ. A ṣàfihàn wọn ní ipò olùwà, àbọ-ọrọ-iṣe àti àbọ ọrọ-atọkùn ní ìhun oníbùú. Àpẹẹrẹ: 3a) Bọlá àti Ọlá ra ilé kan b) Wọn rí ọkọ àti aya ní ibẹ d) Olú ra bàtà fún Ayọ àti Dàda 4a) Tọlá pẹlú Lọlá jẹ ọmọ gidi b) Mo ní Bàbá pẹlú Ìyá d) Mo rà á fún Tolú àti Ẹrín ii) Ọrọ-arọpò orúkọ gígùn + ọrọ-arọopò-orúkọ gígùn (AROG +AROG): àwọn ọrọ-àsopọ wọnyí tún lè ṣiṣẹ gẹgẹ bí àsopọ fún ọrọ arọpò orúkọ gígùn méjì. Gbogbo àwọn AROG yìí jẹ mẹfà. Àbùdá ẹni àti iye ni a lè fi dá wọn mọ tí wọn fi farajọ àwọn ọrọ-arọpò orúkọ kúkúrú. Ṣùgbọn, wọn yàtọ sí AROG pẹlú àbùdá ìtẹnumọ tíí ṣe apàlà wọn (Abimbola, 2019). 5a) Ẹyin àti èmi ni a jẹ tẹtẹ náà b) Wọn sọrọ nípa ìwọ àti èmi d) Àwọn òṣèré náà yóò pidán fún ẹyin àti àwa ní alẹ 6a) Ẹyin pẹlú òun náà ni wọn sọ b) Wọn kìlọ fún àwọn pẹlú àwa d) Ó fẹ bá èmi pẹlú ẹyin ṣeré iii) Ọnà kẹta tí a tún lè gbà lò wọn ni a lè pín sí méjì bí a ṣe fi hàn ní ìsàlẹ yìí: a) Ọrọ-arọpò orúkọ gígùn + ọrọ-orúkọ (AROG+OR): A lè lo àwọn ọrọ-àsopọ náà nípa síso ọrọ- arọpọ-orúkọ gígùn pọ mọ ọrọ-orúkọ. Níbi tí AROG yóò ti ṣáájú tí ọrọ-orúkọ yóò tẹle. Àpẹẹrẹ; 7a) Àwa àti/pẹlú Ayọ san owó wa b) Bàbá rí ẹyin àti/pẹlú Adé d) Wọn sọrọ sí èmi àti/pẹlú Olú b) Ọrọ-orúkọ + ọrọ-arọpò orúkọ gígùn (OR+AROG): Yàtọ sí fífi àti tàbí pẹlú so ọrọ pọ bí a ṣe rí lókè yìí, ọrọ-orúkọ lè ṣáájú kí a sì so pọ mọ ọrọ-arọpọ-orúkọ gígùn. 8a) Adé àti/pẹlú òun ní ó dára b) Ṣé mo sọrọ burúkú sí Ṣọlá àti ìwọ ní àná d) Ó rí Adé Àkànkẹ àti/pẹlú èmi ní ìrònà iv) Àpólà atọkùn + àpólà atọkùn (APAT +APAT): Yatọ sí àpólà orúkọ ní sísopọ, àpólà atọkùn méjì náà lè di síso pọ pẹlú lílo àti tàbí pẹlú. Ọrọ-àsopọ náà yóò dúró sáárín àpólà atọkùn méjì náà. Àpẹẹrẹ; 9a) Wọn gbé orọ ní àdúgbò wa ní àná àti/*pẹlú ní ìjẹta b) Ní pàlàbà àti/*pẹlú ní bọrọgidi ní gbẹ àwọn igi náà Journal of Indigenous Languages (JIL) 178 of 185 v) Ọnà mìíràn tí a tún lè gbà lo àti àti pẹlú ni kí a ka ọrọ-orúkọ ní ọwọọwọ tí yóò wá jẹ pé èyí tó kẹyìn ni a o fi ọrọ-àsopọ náà sí níwájú. Àpẹẹrẹ; 11a) Mo ra ilá, ẹgúsí, ata àti pọnmọ b) Ìsọrí ọrọ ni ọrọ-orúkọ, ọrọ-ìṣe, ẹyán, àti ìyísódì d) Èmi, ìwọ, òun àti ẹyin ni wọn dárúkọ e) Bàbá, ìyá, ọmọ, ará, àti ojúlùmọ wà ní gbàgede ẹ) Bọlá, tọlá, Fọlá àti èmi wà ní agbo náà. g) Fọlá ra bàtà, aṣo, àpò àti nǹkan ọbẹ mìíràn Ọwọ àwọn ìsọrí tí a tò jọ sókè wọnyí nìkan ni wọn ń so pọ. Gẹgẹ bí a ti sọ ní ìṣáájú, ọrọ-ìṣe, ọrọ- atọkùn, wúnrẹn aṣáájú-ìṣe, ọrọ-àpèjúwe, ẹyán, wúnrẹn ìyísódì, àti àwọn aṣegbólóhùn ni a kì í fi àwọn ọrọ-àsopọ méjèèjì wọnyí so pọ. Ní ti ìtumọ, àwọn méjèèjì ni wọn ń ṣàfihàn ìbáṣepọ láàárín ọrọ méjì tàbí jù bẹẹ lọ gẹgẹ bí ìṣesí ọrọ- àsopọ. Ṣùgbọn ó dà bí pé “pẹlú” kì í ṣe lò bi ti “àti” ní àwọn sàkánì kan náà. Gẹgẹ bí àpẹẹrẹ: • A lè lo àti láti fún wa ní ìtumọ onítẹnumọ-ṣísẹ-n-tẹlé. Ìyẹn ni pé, ìtẹnumọ máa ń farahàn ní ṣísẹ-n-tẹlé. Ní irú ìlò yìí, àwọn elédè Yorùbá sábà máa ń kan ọrọ-àsopọ “àti” mọ ọrọ-orúkọ. Gẹbẹ bí àpẹẹrẹ: 11a) Àtèní, àtọla, àtọjọ gbogbo ni elédùmarè yóò máa wà. b) Àtàná, àtòní, àtọla kò sí ìyàtọ. d) Àtọkọ, àtaya ni wọn kó riyẹriyẹ lọ. e) Àtitàná, àtitòní ni mo máa gbà lọwọ rẹ. ẹ) Àtèmi, àtìwọ, àtòun ni a gbọdọ ṣe ara-wa lọkan. Ṣùgbọn kò dàbí pé a lè lo “pẹlú” bẹẹ gẹgẹ bí àwọn gbólóhùn kòbẹgbẹmu ìsàlẹ wọnyí ti fi hàn. 12a) *pẹlánàá, pẹlónìí kò sí èyí tó ṣẹyìn mi b) ?pẹlọkọ pẹláya náà dáa. • A lè lo àti láti fi ìtumọ alálòpọ hàn tí “pẹlú” kò sì ṣe é lò bẹẹ. Àpẹẹrẹ: 13a) Àti arúgbó àti omidan ń kùlùbọ ìdí. b) Àti ọkùnrin àti obìnrin ni wọn máa ń kópa nínú ọdún náà. d) *Pẹlú arúgbọ pẹlú omidan ń kùlùbọ ìdí • Ó dà bí pé “pẹlú” ń ṣiṣẹ gẹgẹ bí ọrọ atọkùn. 14a) Bàbá pẹlú àwọn àbúrò rẹ ni ọrọ kàn. Mo pẹlú wọn nígbà tí wọn ń sọrọ. b) Wọn sọrọ kan pẹlú bàbá náà nípa ọmọ náà. d) Wọn rí ọmọ náà pẹlú òkú àdìyẹ lẹgbẹẹ ọnà. • A sábà máa ń lo “àti” fún ìsọdorúkọ láti ṣẹdá ọrọ-orúkọ tuntun. Ṣùgbọn kò dájú pé a lè lo “pẹlú” bẹẹ. Dípò bẹẹ, a lè fi “pẹlú” sí iwájú àwọn ọrọ tí a ṣẹdá látara “àti”. 15a) àtijẹ, àtimu, àtiná, àtilò b) pẹlú àtijẹ, pẹlú àtiná, pẹlú àtilò b) *pẹlújẹ, Journal of Indigenous Languages (JIL) 179 of 185 • A lè lo àti pẹlú ìsọdorúkọ tí a lo pé láti ṣẹdá. ṣùgbọn kò dá pé a lè lo pẹlú bi èyí láìfa pé kí olùgbọ máa rò pé aláìgbédè ni olùsọ. Gẹgẹ bí àpééré: 16a) àti pé o lọ, àti pé o ò lọ kò kàn mí b) àti pé wọn rán àpò náà àti pé wọn ò rán, bí ó bá sọnù, ìwọ ni wọn ó mú. d) àti pé o ò ní sí ń bẹ kò da nǹkan kan. e) *pẹlú o lọ, pẹlú o ò lọ kò kàn mí Àkíyèsí kan tí ó wà nínú èyí ni pé, bí ẹni gbé gbólóhùn alápòólà orúkọ atakora méjì sẹgbẹẹ ara wọn ni ó rí. A lè lo awẹ kejì láfi awẹ àkọkọ sí iní ìhun náà, àmọ gbogbo awẹ kejì ni ó gbọdọ jẹ ìhun ìyísódì. • Àti ni a sáábà máa ń lò nínú ìkàlọwọọwọ ọrọ-orúkọ. Ìyẹn ni pé bí a bá ń dárúkọ ọrọ-orúkọ ní ìkọọkan, a lè lo “àti” láti fi so gbogbo wọn pọ. Gẹgẹ bí àpẹẹrẹ: 17a) Ìrẹsì, ẹyin, ata, àti ẹran b) Àga, tábìlì, pẹpẹ, àti igi • A máa ń lo “àti” nínú ìhun awẹ-ìsopọ nínú àpólà orúkọ. Ìyẹn ni pé, mọọn-nú ni awẹ tàbí abala tí a gé kúrò yóò jẹ fún àtolùgbọ àtolùsọ. 18a) Àtèmi náà ni wọn ń sọ b) Àti gbogbo ìlú ni wọn pẹ sí ibi ayẹyẹ náà. d) Àti ààrè ni wọn yẹ sí. Gbogbo àkíyèsí àti àpèjúwe yìí ni ó fi hàn pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni a lè lo “àti” àti “pẹlú” gẹgẹ bí pàṣípààrọ ara wọn tàbí kí a sọ pé gbogbo ìgbà kọ ni a lè lò wọn gẹgẹ bí àrọ-ọrọ fún ara wọn láìpàdánù ìtumọ ìhun náà. Ṣùgbọn, “àti” ni a lè lò fàlàlàfalala bí ó ṣe wù wá. Tàbí “Tàbí” dàbí “ṣùgbọn/àmọ” ni. Ohun tí ó yà á sọtọ sí wọn ni pé kì í so èrò inú gbólóhùn pọ. Èyí tàbí ìyẹn ni ó máa ń fi hàn. Ìyẹn ni pé, ìlò rẹ jọ “àti/pẹlú”, òun kàn ń fi ìlò yíyan ọkan nínú ohun méjì tí ó lè jẹ ọrọ-orúkọ, àpólà orúkọ, àpólà atọkùn, àti AROG tí ó bá dúró láàárín wọn. Kì í ṣe pé òye sísopọ gan-an ni tirẹ, tirẹ ni pé èèyàn kò le è mú ohun méjì náà pọ àfi ọkan. Èyí ni pé “yan ìkan nínú ohun méjì náà” ni ìtumọ rẹ. Àpẹẹrẹ: 19a) Ilé tàbí owó b) Èyí tàbí ìyẹn d) Ipò tàbí ọlá 20a) Ìwọ tàbí èmi b) Àwa tàbí àwọn 21a) Bàbá àgbà tàbí ọkùnrin dúdú náà máa sọrọ lórí ọrọ náà. b) Agbádá ńlá tàbí ẹsikí fẹrẹgẹdẹ ni mo máa wọ wá. d) Ọkọ bọgìnnì tàbí ọkọ akérò e) ìyá arúgbó tàbí ọmọbìnrin ọpẹlẹńgẹ 22a) Ní àná tàbí ní òní Journal of Indigenous Languages (JIL) 180 of 185 b) Ǹjẹ ìwé náà wà fún àwọn ọdọ tàbí fún àwọn màjẹsín? d) Fi òògùn náà sí ojú tàbí sí imú Ọrọ àsopọ yìí náà ní àwọn òté tó de ìlò rẹ nínu ìhun gírámà èdè Yorùbá. • Òté àkọkọ ni ó níí ṣe pẹlú ìtumọ ohun tí àsopọ yìí ń ṣe. Ìyẹn ni pé, ó ń ṣàfihàn ohun méjì tí kò ṣe é gbà pọ tàbí tí kò ṣe é yàn pọ lẹẹkan ṣoṣo. Ọkan ni èèyàn gbọdọ yàn nínú nǹkan méjèèjì náà tí ó pàtẹ rẹ. • Bí ìṣesí àti ìtumọ rẹ ti jọ “ṣùgbọn/àmọ” tó, kì í so gbólóhùn pọ. Ọrọ-orúkọ, àpólà orúkọ tàbí àpólà atọkùn ni ó máa ń so pọ bíi ti “àti/pẹlú”. • Àárín ìhun méjì tí o ń só pọ náà ni ó ti máa ń jẹ yọ. Ọrọ Asojúsòdìpọ Irúfẹ àwọn ọrọ wọnyí ni a tún lè pè ní ọrọ asèjì-èròpọ (a-so-èjì-èrò-pọ) tí wọn máa ń fi èrò mejì ọtọọtọ sí ẹgbẹ ara wọn ṣùgbọn tí èrò wọn lè má tèlé ara wọn tàbí kí wọn jẹ ojú àti òdì ara wọn. Àfi/àyàfi Èyí ni àwọn ọrọ tí a lè lò láti so èjì èrò pọ ṣùgbọn tí ó jẹ pé èrò tàbí gbólóhùn kejì gan-an ni a ń retí pé kí ó ṣe tàbí kó fìdí múlẹ kí èrò inú tàkọkọ tó lè wáyé. Ìyẹn ni pé, dandan ni kí gbólóhùn kejì ó ṣelẹ kí ti àkọkọ tó lè dúró. Gbólóhùn kejì ni èrèdí tàbí òté fún ìmúṣẹ gbólóhùn àkọkọ ní ibi tí a bá ti lo “àfi/àyàfi”. Yàtọ sí èyí, òdì ni gbólóhùn àkọkọ máa ń jẹ sí èkejì. Àpẹẹrẹ: 23a) Adébọlá kò níi lọ àfi/àyàfi bí ó bá rí Tolú ọrẹ rẹ b) Kò ní tẹlé ọ àfi/àyàfi bí ó bá rí ẹgbọn rẹ. d) Àwọn òṣìṣẹ kò ní padà sẹnu iṣẹ àfì/àyàfi bí ìjọba bá fún wa ní ẹkúwó e) Lọlá kò ṣetán láti rinsẹ àfi/àyàfi bí Tọlá bá máa lọ. A lè lo “àfi” ní ìbẹrẹ gbólóhùn láìsí gbólóhùn tí a so ó mọ ní ìbẹrẹ rẹ. Ṣùgbọn ó wọpọ láti máa lo “àfi” báyìí dáadáa ju “àyàfi” lọ. Àmọ, bí a bá lo “àyàfi” báyìí, yóò fún wa ní ìtumọ ìtẹnumọ ju ti “àfi” lọ. Àpẹẹrẹ: 24a) àfi bí o bá fẹ jẹ ẹran tútù b) àfi bí o bá fún mi ní owó mi. f.w. d) àyàfi bí ó bá fún mi ní owó mi. Àwọn òté tó de ìlò “àfi/àyàfi” tí a lè tọka sí ni • Òté àkọkọ tí ó de ìlò “àfi/àyàfi” ni pé, gbólóhùn àkọkọ gbọdọ jẹ òdì ti èkejì tí ó wà nínú ìhun tí ọrọ-àsopọ náà ń so pọ. • Òmíràn tún ni pé, gbólóhùn kejì ni èrèdí tàbí àtẹgùn fún ìmúṣẹ ohun tí ti àkọkọ ń sọ. Ìyẹn ni pé láì sí gbólóhùn kejì, ìjóòtọ èrò ti àkọkọ kò ṣe é ṣe. • Bákan náà, gbólóhùn kejì sábà máa ń bẹrẹ pẹlú “bí nǹkan bá rí báyìí”. Ìyẹn ni pé, “bí” jẹ atọka ìṣẹlẹ tinú gbólóhùn kejì. Àmọ àti Ṣùgbọn Àwọn wọnyí ni ọrọ a-so-èjì-èrò-pọ tí ìlò wọn wọpọ jù ní ìsọrí yìí. Kódà, nítorí pé wọn máa ń jẹ yọ pẹlú ìrísí wọn láàárín gbólóhùn méjì, àwọn méjèèjì ni àwọn onímọ kan ń pè ní ọrọ-àsopọ gbólóhùn. A lè lò wọn ní pàṣípààrọ láì ba ìtumọ gbólóhùn wọn jẹ. Èrò inú gbólóhùn àkọkọ máa ń jẹ òdì gbólóhùn kejì. Èrò méjì sábà máa ń jẹ alójúlódì tàbí aṣelòdì arawọn.